Hymn 232 Jesu ore elese ku Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Jesu ore elese ku,
Awon omo Salem nsokun:
Okunkun bo oju orun,
Isele nla se lojiji.
2 Nihin l’ a r’ anu at’ ife,
Oba ogo ku f’ enia;
Wo! ayo ki l’ a tun ri yi,
Jesu t’ O ku tun ji dide.
3 Ma beru mo, enyin mimo;
So bi Oluwa ti joba;
Korin b’ O ti segun Esu,
Bi O si ti bori iku.
4 E wipe, “Oba, wa titi,
Iwo t’ a bi lati gba wa;”
K’ e b’ iku pe, “Oro re da?”
“Iboji, isegun re da?” Amin.