Hymn 471 Olorun ite ogo Re Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olorun ite ogo Re,
Yio wa titi lai;
Obi wa, talaka ni nwon,
F’ ibukun Re fun wa.
2 O wu O ni, lati se wa,
Ni talaka; sugbon
Ma se alabojuto wa,
’Gba ti a wa l’ aiye.
3 A mo, b’ a tile je Tire,
T’ a j’ oruko mo O,
A j’ alejo; sugbon se wa
L’ omo asayan Re.
4 Oluso Agutan wa, wo
Agbo kekere Re;
F’ ogo at’ opa Re to wa,
Omo agbo Tire. Amin.