Hymn 375 Ha! Egbe mi, e w’ asia Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ha! Egbe mi, e w’ asia
Bi ti nfe lele!
Ogun Jesu fere de na,
A fere gun!
D’ odi mu, emi fere de,”
Beni Jesu nwi,
Ran ‘dahun pada s’ orun , pe,
Awa o dimu.
2 Wo opo ogun ti mbo wa,
Esu nko won bo;
Awon alagbara nsubu,
A fe damu tan!
D’ odi mu, &c.;
3 Wo asia Jesu ti nfe;
Gbo ohun ipe;
A o segun gbogbo ota
Ni oruko Re.
D’ odi mu, &c.;
4 Ogun ngbona girigiri,
Iranwo w ambo;
Balogun wa mbo wa tete,
Egbe, tujuka!
D’ odi mu, &c.; Amin.