Hymn 176 Elese, e yipada Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Elese, e yipada,
Ese ti e o fi ku ?
Eleda nyin ni mbere,
T’ o fe ki e ba On gbe;
Oran nla ni o mbi nyin,
Ise owo Re ni nyin,
A ! enyin alailope,
Ese t’ e o ko ’fe Re ?
2 Elese, e yipada,
Ese ti e o fi ku ?
Olugbala ni mbere,
Enit’ o gb’ emi nyin la;
Iku Re y’o jasan bi ?
E o tun kan mo ’gi bi ?
Eni ’rapada, ese
Ti e o gan ore Re ?
3 Elese, e yipada,
Ese ti e o fi ku ?
Emi Mimo ni mbere,
Ti nf’ ojo gbogbo ro nyin;
E ki o ha gb’ ore Re ?
E o ko iye sibe ?
A ti nwa nyin pe, ese
T’e mbi Olorun ninu ?
4 Iyemeji ha nse nyin
Pe, ife ni Olorun,
E ki o ha gb’ oro Re ?
K’ e gba ileri Re gbo ?
W’ Oluwa nyin lodo nyin,
Jesu nsun: w’omije Re;
Eje Re pelu nke, pe,
“Ese ti e o fi ku ?” Amin.