Hymn 172 Bi mo ti ri laisawawi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Bi mo ti ri laisawawi,
Sugbon nitori eje Re;
B’o si ti pe mi pe ki mwa
Olugbala, mo de.
2 Bi mo ti ri laiduro pe,
Mo fe k’okan mi mo toto,
S’odo Re t’o le we mi mo,
Olugbala, mo de.
3 Bi mo ti ri b’o tile je
Ija l’ode, ija ninu,
Eru l’ode eru ninu,
Olugbala, mo de.
4 Bi mo ti ri osi, are,
Mo si nwa imularada;
Iwo l’o le s’awotan mi,
Olugbala, mo de.
5 Bi mo ti ri ’Wo o gba mi,
Wo o gba mi t’owo t’ese;
’Tori mo gba ’leri Re gbo,
Olugbala, mo de.
6 Bi mo ti ri ife Tire,
L’o sete mi patapata;
Mo di tire, tire nikan,
Olugbala, mo de. Amin.