Hymn 113 Irawo wo l’eyi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Irawo wo l’eyi ?
Wo b’ o ti dara to,
Amona awon keferi
S’ odo Oba ogo.
2 Wo awon amoye
Ti ila- orun wa;
Nwon wa fi ori bale fun
Jesu Olubukun.
3 Imole ti Emi,
Ma sai tan n’ ilu wa;
Fi ona han wa k’ a le to,
Emmanueli wa.
4 Gbogbo irun- male,
Ati igba- male,
Ti a mbo n’ ile keferi,
K’ o yago fun Jesu.
5 Ki gbogbo Abore
Ti mbe ni Afrika,
Je amoye li otito,
Kin won gb’ ebo Jesu.
6 Baba Eleda wa,
Ti o fi Jesu han
Awon keferi igbani;
Fi han fun wa pelu. Amin.