Hymn 541 Lekan k’a to tuka Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Lekan k’a to tuka,
Je k’a yin Oluwa!
Ki okan at’ ahon,
F’ iyin f’ oruko Re;
Jesu, ore ’elese,
Enit’ okan wan yin;
Iyin Re ko lopin,
E yin titi lailai.
2 N’nu Oro mimo Re,
L’ awa o ma dagba;
K’a ma mo Oluwa,
K’a se eyi t’ a mo.
Jesu ore ’elese, &c.; Amin.