Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 595 F’ awon Ijo ti nsimi Lyrics

Hymn 595 F’ awon Ijo ti nsimi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 F’ awon Ijo ti nsimi,
Awa Ijo t’ aiye;
A f’ iyin gbogbo fun O,
Jesu Olubukun;
Oluwa, O ti segun,
Ki nwon ba le segun;
’Mole ade ogo won,
Lat’ odo Re wa ni.

St. Anderu.

A yin O, fun ’ranse Re,
Ti o ko j’ ipe Re:
T’o mu arakonrin re
Wa, lati ri Kristi;
Pese okan wa sile,
K’a sona lodun yi,
K’a m’ awon ara wa wa,
Lati ri bibo Re.

St. Tomasi.

A yin O, fun ’ranse Re,
T’ iseyemeji re,
F’ ese ’gbagbo wa mule,
T’ o si fi ’fe Re han;
Oluwa f’ alafia
F’awon ti nreti Re;
Je k’a mo O lotito,
L’ enia at’ Olorun.

St. Stefanu.

A yin O, fun ’ranse Re,
Ajeriku ’kini:
Eni, ninu wahala,
T’o nkepe Olorun;
Oluwa, b’o ba kan wa
Lati jiya fun O,
L’aiye, je k’a jeri Re,
L’ orun, je k’a gb’ ade.

St. Johannu Onihinrere.

A yin O, fun ’ranse
L’ erekusu Patmo,
A yin O, f’ eri toto,
Ti o je nipa Re.
A yin O, fun iran na,
Ti O fihan fun wa;
A o fi suru duro,
K’ a le ka wa mo won.

Ojo awon Omo were ti a pa.

A yin O, f’awon ewe,
Ajeriku mimo;
A si won lowo ogun,
Lo sibi isimi;
Rakeli, ma sokun mo,
Nwon bo lowo ’rora:
F’ okan ailetan fun wa,
K’ a gb’ ade bi ti won.

Iyipada ti St. Paulu.

A yin O, fun imole
At’ ohun lat’ orun,
A si yin O, fun iran,
Ti abinuku ri;
Ati fun ’yipada re,
A fi ogo fun O
Jo, tan ina Emi Re,
Sinu okunkun wa.

St. Mattia.

Oluwa, Iwo t’ o wa.
Pel’ awon t’ o pejo;
Iwo t’o yan Mattia
Lati ropo Juda:
A’ mbe O, gba Ijo Re
Lowo eke woli;
Rant’ ileri Re, Jesu,
Pelu ’jo Re dopin.

St. Marku.

A yin O fun ’ranse Re,
T’ Iwo f’ agbara fun;
Enit’ ihinrere re
Mu orin ’segun dun;
Ati n’nu ailera wa,
Jo je agbara wa;
Je k’a s’ eso ninu Re,
Iwo Ajara wa.

St. Filippi ati St. Jakobu.

A nyin O fun ’ranse Re,
Fillipi amona;
Ati f’ arakonrin Re,
Se wa l’ arakonrin;
Masai je k’ a le mo O,
Ona, Iye, Oto;
K’ a jeju ko idanwo,
Titi ao fi segun.

St. Barnaba.

A nyin O, fun Barnaba,
Enit’ ife Re mu
K’o ko ’hun aiye sile,
K’o wa ohun orun;
Bi aiye ti ngbile si,
Ran emi Re si wa,
Ki itunu Re toto,
Tan bo gbogbo aiye.

St. Johannu Baptisti.

A yin O, f’ Oni- baptis,
Asaju Oluwa;
Elija toto ni ’se,
Lati tun ona se.
Woli t’o ga julo ni,
O ri owuro Re;
Se wa l’ alabukunfun,
Ti nreti ojo Re.

St. Peteru.

A yin O, fun ’ranse Re,
Ogboiya ninu won;
O sebu nigba meta,
O ronupiwada;
Pelu awon alufa,
Lati toju agbo;
Si fun won ni igboiya
At’ itara pelu.

St. Jakobu.

A yin O, fun ’ranse Re,
Eniti Herod pa;
O mu ago iya Re,
O mu oro Re se;
K’ a ko iwara sile,
K’ a fi suru duro;
K’a ka iya si ayo,
B’o ba fa wa mo O.

St. Bartolomeu.

A yin O, fun ’ranse Re,
Eni oloto ni;
Enit’ oju Re ti ri,
Labe ’gi opoto.
Jo, se wa l’ alailetan,
Israeli toto;
Ki O le ma ba wa gbe,
K’ O ma bo okan wa.

St. Matteu.

A yin O, fun ’ranse Re,
T’o so ti ibi Re;
T’o ko ’hun aiye sile,
T’o yan ona iya;
Jo, da okan wa nide,
Lowo ife owo;
Je k’a le je ipe Re,
K’a nde k’a tele O.

St. Luku.

A yin O, f’ onisegun,
Ti ihinrere re,
Fi O han b’ Onisegun,
At’ Abanidaro;
Jo, f’ororo iwosan,
Si okan gbogbo wa,
At’ ikunra ’yebiye,
Kun wa nigbagbogbo.

St. Simoni ati St. Juda.

F’awon iranse Re yi,
A yin O, Oluwa;
Ife kanna l’o mu won,
Lati gb’ ona mimo;
Awa iba le jo won,
Lati gbe Jesu ga:
Ki ife so wa sokan,
K’a de ibi ’simi.

IPARI (GENERAL ENDING).

Apostili, Woli, Martyr,
Awon egbe mimo;
Nwon ko dekun orin won,
Nwon wo aso ala;
F’ awonyi t’o ti koja,
A yin O, Oluwa;
Ao tele ipase won,
A o si ma sin O.

Iyin f’ Olorun Baba,
At’ Olorun Omo,
Olorun Emi Mimo,
Metalokan Mimo;
Awon ti a ra pada,
Y’o teriba fun O;
Tire l’ ola, at’ ipa,
At’ ogo, Olorun. Amin.

Exit mobile version