Hymn 568 Okan mi, yin Oba orun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Okan mi, yin Oba orun,
Mu ore wa s’odo Re;
’Wo t’a wosan t’a dariji,
Tal’ a ba ha yin bi Re?
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Yin Oba ainipekun.
2 Yin, fun anu t’O fihan,
F’awon baba ’nu ponju;
Yin I, okan na ni titi,
O lora lati binu;
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Ologo n’nu otito.
3 Bi baba ni O toju wa,
O si mo ailera wa;
Jeje l’o ngbe wa lapa Re,
O gba lowo ota;
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Anu re yi aiye ka.
4 A ngba b’itana eweko,
T’ afefe nfe, t’o si nro;
’Gbati a nwa, ti a si nku,
Olorun wa bakanna;
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Oba alainipekun.
5 Angel, e jumo ba wa bo,
Enyin nri lojukoju;
Orun, osupa, e wole,
Ati gbogbo agbaiye.
E ba wa yin, E ba wa yin.
Olorun Olotito. Amin.