Hymn 560 E wole f’Oba, Ologo julo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 E wole f’Oba, Ologo julo
E korin ipa ati ife Re;
Alabo wa ni at’ Eni Igbani
O ngbe ‘nu ogo, Eleru ni iyin.
2 E so t’ipa Re, e so t’ore Re;
‘Mole l’ aso Re, kobi Re, orun
Ara ti nsan ni keke ‘binu Re je;
Ipa ona Re ni a ko si le mo.
3 Aiye yi pelu ekun ‘yanu re
Olorun agbara Re l’o da won;
O fi idi re mule, ko si le yi,
O si f’ okun se aso igunwa Re.
4 Enu ha le so ti itoju Re?
Ninu afefe, ninu imole;
Itoju Re wa nin’ odo t’o nsan,
O si wa ninu iri ati ojo.
5 Awa erupe, aw’ alailera
‘Wo l’a gbekele, O ki o da ni;
Anu Re ronu, o si le de opin,
Eleda, Alabo, Olugbala wa.
6 ‘Wo Alagbara, Onife Julo,
B’awon angeli ti nyin O l’oke,
Be l’awa eda Re, niwon t’a le se,
A o ma juba Re, a o ma yin O. Amin.