Hymn 551 Je k’a f’ohun kan korin Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Je k’a f’ohun kan korin,
K’a ma yin Oluwa wa,
O ye k’a f’ iyin fun U,
L’ okan ati l’ ohun wa.
2 O f’ agbara Re da wa,
O pa wa mo di oni;
O rawa lowo iku,
O wa, O si ku fun wa.
3 Ase t’O pa ni k’ a se,
Ona t’O la ni k’a to;
B’ O ti feni, je k’a fe
Enia at’ Olorun.
4 O fe adura ewe,
O si fe iyin ewe;
Je k’a f’okan wa fun U,
A o de ’le oba Re. Amin.