Hymn 543 Fi ibukun Re tu wa ka Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Fi ibukun Re tu wa ka,
Fi ayo kun okan wa;
K’ olukuluku mo ’fe Re,
K’a l’ayo n’nu ore Re:
Tu wa lara, tu wa lara
La aginju aiye ja.
2 Ope at’ iyin l’ a nfun O,
Fun ihinrere ayo;
Je ki eso igbala Re
Po lokan at’ iwa wa:
Ki oju Re, ki oju Re
Ma ba wa gbe titi lo.
3 Nje, nigbat’ a ba si pe wa
Lati f’ aiye yi sile,
K’ Angeli gbe wa lo sorun,
Layo ni k’a jipe na;
K’a si joba, k’a si joba
Pelu Krsiti titi lai. Amin.