Hymn 531 Oluwa, a wa ’do Re Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa, a wa ’do Re,
L’ ese Re l’a kunle si;
A! ma kegan ebe wa,
A o wa O lasan bi?
2 L’ ona ti O yan fun wa,
L’ a nwa O lowolowo;
Oluwa, a ki o lo,
Titi ’Wo o bukun wa.
3 Ranse lat’ oro Re wa,
Ti o fi ayo fun wa;
Je ki Emi Re k’o fun
Okan wa ni igbala.
4 Je k’ a wa, k’a si ri O
Ni Olorun Olore;
W’ alaisan, da ’gbekun si,
Ki gbogbo way o si O. Amin.