Hymn 53 Oluwa agbara fohun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa agbara fohun,
Bi ara l’oke Sinai;
Awon Israeli gbohun Re,
Nwon sig bon fun iberu:
Okunkun su biribiri;
Ati l’otun ati l’osi,
Awon apata nfaya.
2 Oluwa ife je ’rora
L’ori oke Kalfari:
O gbe oju soke orun,
L’akoko wahala Re:
Fun wa l’o ru eru egbe,
Fun wa l’o t’ eje Re sile,
T’o sit u Baba l’oju.
3 Oba ife at’ agbara,
Oluwa eda gbogbo,
O npada bo ninu ogo,
Lati wa gba ijoba;
Ipe y’o dun, angel y’o ho,
Halleluya y’o j’orin won
L’ori Esu at’ iku. Amin.