Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 527 Olorun, awa fe Lyrics

Hymn 527 Olorun, awa fe Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Olorun, awa fe
Ile t’ola Re wa;
Ayo ibugbe Re
Ju gbogbo ayo lo.

2 Ile adura ni,
Fun awa omo Re;
Jesu, O wa nibe,
Lati gbo ebe wa.

3 Awa fe ase Re,
Kil’ o dun to l’ aiye;
Nib’ awon oloto,
Nri O nitosi won.

4 Awa fe oro Re,
Oro alafia;
T’itunu at’ iye,
Oro ayo titi.

5 A fe korin anu,
T’a nri gba l’aiye yi;
Sugbon awa fe mo
Orin ayo t’orun.

6 Jesu, Oluwa wa,
Busi ’fe wa nihin;
Mu wa de ’nu ogo,
Lati yio O titi. Amin.

Exit mobile version