Hymn 516 Igba asale ti dun to Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Igba asale ti dun to!
Ti ara tu ohun gbogbo:
’Gbat’ itansan orun ale
Ba ntanmole s’ ohun gbogbo!
2 Beni ’kehin onigbagbo,
On a simi l’ alafia;
Igbagbo to gbona janjan
A mole ninu okan re.
3 Imole kan mo loju re,
Erin sib o ni enu re;
O nf’ ede t’ ahon wa ko mo
Soro ogo t’o sunmole.
4 Itansan ’mole t’ orun wa,
Lati gba niyanju lona;
Awon angel duro yika
Lati gbe lo s’ibugbe won.
5 Oluwa, je k’ a lo bayi,
K’a ba O yo, k’a r’ oju Re;
Te aworan Re s’ okan wa,
Si ko wa b’ a ti ba O rin. Amin.