Hymn 512 Ona Re, Oluwa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ona Re, Oluwa,
B’o ti wu k’o di to,
Fi owo Re to mi,
Yan ipa mi fun mi.
2 B’o rorun, b’o soro,
Daradara l’o je;
B’o run tab’ o wo ni,
Dandan s’isimi ni.
3 Nko gbodo yan ’pin mi,
Nko tile je yan a;
Yan fun mi, Olorun,
Benin go rin dede.
4 Ijoba t’emi nwa,
Tire ni; je k’ona
T’o re ’be je Tire;
Bi beko ngo sina.
5 Gba, ago mi, fayo
Tab’ ibanuje kun;
B’o ti to l’oju Re,
Yan ’re tab’ ibi mi.
6 Yan ore mi fun mi,
Aisan tab’ ilera;
Yan aniyan fun mi,
Aini tabi oro.
7 Yiyan k’ ise t’emi,
Ninu ohunkohun;
Iwo s’oluto mi,
Ogbon on gbogbo mi. Amin.