Hymn 503 Ire t’ a su ni Eden Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ire t’ a su ni Eden,
N’ igbeyawo ’kini
Ibukun t’a bukun won,
O wa sibe sibe.
2 Sibe titi di oni,
N’ igbeyawo Kristian,
Olorun wa larin wa,
Lati sure fun wa.
3 Ire ki nwon le ma bi,
Ki nwon k’o si ma re;
Ki nwon ni dapo mimo,
T’ enikan k’yo le tu.
4 Ba nip e, Baba, si fa
Obirin yi f’ oko;
Bi O ti fi Efa fun
Adam lojo kini.
5 Ba wa pe Immanueli,
Si so owo won po,
B’ eda meji ti papo
L’ ara ijinle Re.
6 Baw a pe, Emi Mimo,
F’ ibukun Re fun won:
Si se won ni asepe,
Gege b’ O ti ma se.
7 Fin won sabe abo Re,
K’ ibi kan ma ba won;
’Gba nwon npara ile Re,
Ma toju okan won.
8 Pelu won l’ oj’ aiye won,
At’ oko at’ aya;
Titi nwon o de odo Re,
N’ ile ayo l’ orun. Amin.