Hymn 499 Tire titi lai l’ awa se Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Tire titi lai l’ awa se,
Oluwa wa orun;
K’ ohun at’ okan wa wipe,
Amin, beni k’ o ri.
2 ‘Gbati aiye ban dun mo ni,
T’ o si nfa okan wa;
K’ iro yip e, “Tire l’ awa,”
Le ma dun l’ eti wa.
3 ‘Gbat’ ese pelu etan re,
Ba fe se wa n’ ibi;
K’iro yi pe, “Tire l’awa,”
Tu etan ese ka.
4 ‘Gbati Esu ba ntafa re,
S’ ori ailera wa;
K’iro yi pe, “Tire l’ awa,”
Ma je ki o re wa.
5 “Tire”, n’ igb’ a wa l’omode,
“Tire,” n’ igb’ a ndagba,
“Tire,” n’ igba’ a ba darugbo,
Ti aiye wa mbuse.
6 “Tire,” titi lai l’ awa se,
A f’ ara wa fun O:
Titi aiye anipekun,
Amin, beni k’o ri. Amin.