Hymn 496 Oluwa, k’ a ha w’ odo Re Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa, k’ a ha w’ odo Re?
Ebun orun ni a ntoro;
Nigba ti a wa ni ewe,
L’a ti gbe wa wa odo Re,
Fun wa ni ore- ofe Re,
K’ a le to O wa fun ’ra wa.
2 Oluwa, k’ a ha w’ odo Re,
Nigb’ a ba te tabili Re,
T’ a nse apere iku Re,
Ni jij’ akara, mimu wain?
Gb’ adura awon omo Re,
Kin won k’o le ri O nibe.
3 Oluwa, k’ a ha w’ odo Re,?
Ki se nigba yi nikan ni,
Sugbon ni gbogbo ojo wa,
Nigba oro tabi ise
K’a wa s’ idi ’te or’ofe,
K’ a duro sinsin n’ igbagbo.
4 Oluwa, k’ a ha w’ odo Re?
A fe, bere ebun kan si;
Pe, ’gbari aiye ba koja,
Ti ipe ikehin ba dun,
K’ a le w’ odo Re, Oluwa,
K’ a si nipo wa l’ aiya Re. Amin.