Hymn 424 Baba, niwaju ite Re Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Baba, niwaju ite Re,
L’ angeli nteriba;
Nigbagbogbo niwaju Re,
Ni nwon nkorin iyin;
Nwon si nfi ade wura won,
Lele yite na ka;
Nwon nfi ohun pelu duru
Korin si Oluwa.
2 Didan Osumare sin tan
Si ara iye won;
Bi Seraf ti nke si Seraf,
Ti nwon nkorin ’yin Re;
Bi a ti kunle nihinyi,
Ran ore Re si wa;
K’ a mo pe ’Wo wa nitosi,
Lati da wa lohun.
3 Nihin, nibit’ awon Angel
nwo wa b’a tin sin O;
Ko wa k’a wa ile orun,
K’a sin O bi ti won;
K’a ba won ko orin iyin,
K’a ba won mo ’fe Re;
Titi agbara y’o fi di
Tire, Tire nikan. Amin.