Hymn 395 Ko mi Oluwa, bi a ti Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ko mi Oluwa, bi a ti
Je gbohungbohun oro Re;
B’ o ti wa mi, je k’ emi wa
Awon omo Re t’ o ti nu.
2 To mi Oluwa, kin le to
Awon asako si ona;
Bo mi Oluwa, kin le fi
Manna Re b’ awon t’ ebi npa.
3 Fun mi l’ agbara; fie se
Mi mule lori apata;
Kin le na owo igbala
S’ awon t’ o nri sinu ese.
4 Ko mi Oluwa, kin le fi
Eko rere Re k’ elomi;
F’ iye f’ oro mi, ko le fo
De ikoko gbogbo okan.
5 F’ isimi ’didun Re fun mi,
Fi kun mi li opolopo;
Ki ero ati oro mi
Kun fun ife at’ iyin Re.
6 Jesu, fi ekun Re kun mi,
Fi kun mi li opolopo;
Ki ero ati oro mi
Kun fun ife at’ iyin Re.
7 Lo mi, Oluwa, an’ emi,
Bi o ti fe, nigbakugba;
Tit em’ o fi r’ oju Re
Ti ngo pin ninu ogo Re. Amin.