Hymn 393 Wa, ma sise Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Wa, ma sise
Tani gbodo s’ ole ninu oko,
‘Gbati gbogbo enia nkore jo?
Kaluku ni Baba pase fun pe,
“Sise loni.”
2 Wa, ma sise.
Gba ‘pe giga ti angeli ko ni –
Mu ‘hinrere to t’agba t’ewe lo:
“Ra ‘gba pada;” wawa l’akoko nlo.
Ile su tan.
3 Wa, ma sise.
Oko po, alagbase ko si to,
A n’ibi titun gba, a ni ‘po ro;
Ohun ona jijin, at’ itosi,
Nkigbe pe, “wa.”
4 Wa, ma sise.
Le ‘yemeji on aigbagbo jinna,
Ko s’alailera ti ko le se nkan:
Ailera l’Olorun ama lo ju
Fun ‘se nla Re.
5 Wa, ma sise.
‘Simi ko si, nigbat’ ise osan,
Titi orun yio fi wo l’ ale,
Ti awa o si gbo ohun ni pe,
“O seun, omo.”
6 Wa, ma sise.
Lala na dun, ere re si daju.
‘Bukun f’ awon t’ o f’ ori ti d’ opin:
Ayo won, ‘smimi won, y’o ti po to,
Lod’ Oluwa! Amin..