Hymn 39 Emi Olorun alaye Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Emi Olorun alaye,
N’nu ekun ore- ofe Re,
Nibiti’ ese enia ti te,
Sokale sori iran wa.
2 F’ebun ahon, okan ife,
Fun wa lati soro ’fe Re,
K’ibukun at’agbara Re,
Ba l’awon t’o ngbo oro na.
3 K’okun kase ni bibo Re:
Ki darudapo di tito;
F’ilera f’okan ailera;
Je ki anu bori ’binu.
4 Emi Olorun, jo pese
Gbogbo aiye fun Oluwa;
Mi si won b’afefe oro,
K’ okan okuta le soji.
5 Baptis’ gbogb’ orile- ede;
Rohin ’segun Jesu yika;
Yin oruko Jesu logo
Tit’ araiye yio jewo Re. Amin.