Hymn 387 Ao sise! ao sise! om- Olorun ni wa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ao sise! ao sise! om- Olorun ni wa,
Je k’a tele ipa ti Oluwa wa to;
K’a f’ imoran Re so agbara wa d’otun,
K’a fi gbogbo okun wa sise t’a o se,
Foriti! foriti
Ma reti, ma sona,
Titi Oluwa o fi de.
2 Ao sise! ao sise! bo awon t’ebi npa,
Ko awon alare lo s’ orison iye!
Ninu agbelebu l’awa o ma sogo,
Gbati a ba nkede pe, “Ofe n’ Igbala.”
Foriti, &c.;
3 Ao sise! ao sise! l’ agbara Oluwa,
Ijoba okunkun at’ iro yio fo,
A o sig be oruko Jehofa leke,
N’nu orin iyin w ape, “Ofe n’ Igbala.”
Foriti, &c.;
4 Ao sise! ao sise! l’ agbara Oluwa,
Agbada at’ ade y’o si je ere wa;
’Gbat’ ilea won oloto ba di tiwa,
Gbogbo wa o jo ho pe, “Ofe n’ Igbala.”
Foriti! foriti!
Ma reti, ma sona,
Titi Oluwa o fi de. Amin.