Hymn 353 Jesu, mo gb’ agbelebu mi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Jesu, mo gb’ agbelebu mi,
Kin le ma to O lehin;
Otosi at’ eni egan,
‘Wo l’ ohun gbogbo fun mi:
Bi ini mi gbogbo segbe,
Ti ero mi gbogbo pin;
Sibe oloro ni mo je!
Temi ni Krist’ at’ Orun.
2 Eda le ma wahala mi,
Y’o mu mi sunmo O ni;
Idanwo aiye le ba mi,
Orun o mu ‘simi wa.
Ibanuje ko le se nkan
B’ ife Re ba wa fun mi;
Ayo ko si le dun mo mi,
B’ Iwo ko si ninu re.
3 Okan mi, gba igbala re,
Bori ese at’ eru.
F’ ayo wa ni ipokipo,
Ma sise, si ma jiya:
Ro t’ Emi t’o wa ninu re;
At’ ife Baba si O;
W’ Olugbala t’o ku fun o;
Omo orun, mase kun!
4 Nje koja lat’ ore s’ ogo,
N’n adura on igbagbo;
Ojo ailopin wa fun O,
Baba y’o mu o de ‘be.
Ise re laiye fere pin,
Ojo ajo re mbuse,
Ireti y’o pada s’ ayo,
Adura s’ orin iyin. Amin.