Hymn 346 Alabukun ni fun ife Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Alabukun ni fun ife,
Ti ki o je k’ a ya;
Bi ara wa jina s’ ara,
Okan wa wa l’ okan.
2 Da opo Emi s’ ori wa,
Ona t’ o la l’ a nto;
Nipa ti Jesu l’ a si nrin,
Iyin Re l’ a nfi han.
3 Awa ba ma rin l’ ona Re,
K’ a ma si m’ ohun kan,
K’ a ma fe ’hun kan, bikose,
Jesu t’ a pa fun wa.
4 K’ a sunmo O girigiri,
Ati si ona Re;
K’ a ma r’ ore gba l’ odo Re,
Ekun ore- ofe. Amin.