Hymn 311 Alafia, li laiye ese yi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Alafia, li laiye ese yi?
Eje Jesu nwipe, “Alafia.”
2 Alafia, ninu opo lala?
Lati se ife Jesu, ni ’simi.
3 Alafia, n’nu igbi banuje?
L’ aiya Jesu ni dake roro wa.
4 Alafia, gb’ ara wa wa l’ajo?
Ni ’pamo Jesu, iberu ko si.
5 Alafia, b ’a ko tile m’ ola?
Sugbon a mo pe Jesu wa lailai.
6 Alafia, nigb’ akoko iku?
Olugbala wa ti segun iku.
7 O to: jakadi aiye fere pin,
Jesu y’o pe wa s’ orun Alafia. Amin.