Hymn 303 Aigbagbo, bila ! temi l’ Oluwa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Aigbagbo, bila ! temi l’ Oluwa,
On o si dide fun Igbala mi;
Ki nsa ma gbadura, On o se ranwo;
‘Gba Krist wa lodo mi, ifoiya ko si.
2 B’ona mi ba su, On l’o sa n to mi,
Ki nsa gboran sa, On o si pese;
Bi iranlowo eda gbogbo saki,
Oro t’ enu Re so y’o bori dandan.
3 Ife t’o nfi han ko je ki nro pe,
Y’o fi mi sile ninu wahala;
Iranwo ti mo si nri lojojumo,
O nki mi laiya pe, emi o la ja.
4 Emi o se kun tori iponju,
Tabi irora? O ti so tele!
Mo m’ oro Re p’awon ajogun ‘gbala,
Nwon ko le s’ aikoja larin wahala.
5 Eda ko le so kikoro ago
T’ Olugbala mu, k’ elese le ye;
Aiye Re tile buru ju temi lo,
Jesu ha le jiya, k’ emi si ma sa!
6 Nje b’ ohun gbogbo ti nsise ire,
Adun n’ ikoro, onje li ogun;
B’ oni tile koro, sa ko ni pe mo,
Gbana orin ‘segun yio ti dun to!.Amin.