Hymn 302 Iwo Isun imole Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
APA I
1 Iwo Isun imole;
Ogo ti ko l’ okunkun;
Aiyeraiye, titi lai,
Baba Mimo, gbo ti wa.
2 Kanga Iye tin san lai;
Iye ti ko l’ abawon,
Iye t’ o ni irora,
Baba Mimo, gbo ti wa.
3 Olubukun, Olufe,
Omo Re mbe O loke;
Emi Re nrado bo wa;
Baba Mimo, gbo ti wa.
4 Y’ ite safire Re ka
L’ osumare ogo ntan;
O kun fun Alafia,
Baba Mimo, gbo ti wa.
5 N’ iwaju ’te anu Re
L’ awon Angeli npade,
Sugbon wow a lese Re,
Baba Mimo, gbo ti wa.
6 Iwo ti okan Re nyo
S’ amusua t’ o pada,
T’O mo ’rin re lokere,
Baba Mimo, gbo ti wa.
7 Okan ti nwa isimi;
Okan t’ eru ese npa;
B’ om’- owo ti nke f’ omu,
Baba Mimo, gbo ti wa.
8 Gbogbo wa ni alaini
L’ ebi, l’ ongbe at’ are;
Ko si ede f’ aini wa,
Baba Mimo, gbo ti wa.
9 Isura opolopo
Ko l’O kojo bi Oba?
Ainiye, aidiyele?
Baba Mimo, gbo ti wa.
10 ’Wo ko da Omo Re si,
Omo Re kansoso na,
Tit’ O fi par’ ise Re,
Baba Mimo, gbo ti wa.
APA II
1 ’Wo t’O sunmo, gb’ O nkedun,
T’O gbo ’gbe Re ikehin;
T’O jowo Re lati ku.
Baba Mimo, gbo ti wa.
2 Iwo ti o le gba ni
L’owo iji iparun,
L’owo ’boji at’ iku.
Baba Mimo, gbo ti wa.
3 ’Wo low’ otun Eniti
On joko nisisiyi,
T’O gunwa bi t’ isaju
Baba Mimo, gbo ti wa.
4 ’Wo t’O f’ ore de l’ade,
T’O si gbe mo aiya Re,
On n’ Imole oju Re.
Baba Mimo, gbo ti wa.
5 Gbogb’ ebun meje orun,
Lodo Emi meje ni
A fi won fun l’ ainiwon
Baba Mimo, gbo ti wa.
6 L’ase Re ni Emi wa,
’Mole at’ ela ahon,
L’oko Olurapada.
Baba Mimo, gbo ti wa.
7 Fun wa li akoko yi,
Lat’ inu ebun Re wa,
’Mole, iye, agbara.
Baba Mimo, gbo ti wa.
8 Gbo ’gbe wa, gbo aini wa;
Gbo, Emi mbebe n’nu wa:
Gbo, tori Jesu nsipe.
Baba Mimo, gbo ti wa. Amin.