Hymn 301 Oju kan mbe ti ki togbe Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oju kan mbe ti ki togbe,
Nigbat’ ile bas u;
Eti kan si mbe ti ki ise,
‘Gbati orun ba wo.
2 Apa kan mbe, ti ko le re,
‘Gba ‘pa enia pin;
Ife kan mbe, ti ko le ku,
‘Gba ‘fe aiye ba ku.
3 Oju na wno awon Seraf,
Apa na d’ orun mu;
Eti na kun f’ orin Angel,
Ife na ga loke.
4 Ipa kan l’ enia le lo,
‘Gbat’ ipa gbogbo pin;
Lati ri oju at’ apa,
Ati ife nla na.
5 Ipa na ni adura wa,
Ti nlo ‘waju ite;
T’o nmi owo t’o s’aiye ro,
Lati mu gbala wa.
6 Iwo t’anu Re ko lopin,
T’ife Re ko le ku;
Je k’a n’ igbagbo at’ ife,
K’a le ma gbadura. Amin.