Hymn 300 Lo, l’ oro kutukutu Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Lo, l’ oro kutukutu,
Lo, ni osangangan,
Lo, ni igba asale,
Lo, ni oganjo or;
Lo’ t’ iwo t’ inu rere
Gbagbe ohun aiye,
Si kunle n’ iyewu re,
Gbadura nikoko,
2 Ranti awon t’ o fe o,
At’ awon t’ iwo fe;
Awon t’ o korira re,
Si gbadura fun won;
Lehin na, toro ’bukun,
Fun ’wo tikalare;
Ninu adura re, ma
Pe oruko Jesu.
3 B’ aye ati gbadura
Nikoko ko si si,
T’ okan re fe gbadura,
’Gbat’ ore yi o ka,
’Gbana, adura jeje
Lat’ inu okan re
Y’o de odo Olorun,
Olorun alanu.
4 Ko si ayo kan l’ aiye,
T’ o si ju eyi lo;
Nit’ agbara t’ a fun wa,
Lati ma gbadura;
’Gbat’ inu re ko ba dun,
Je k’ okan re wole;
Ninu ayo re gbogbo,
Ranti or’ofe re. Amin.