Hymn 290 Bawo ni awon ewe wa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Bawo ni awon ewe wa,
Y’o ti ma sora won?
Bikose “nipa ’kiyesi,
Gege bi oro Re.”
2 ’Gba oro na wo ’nu okan,
A tan imole ka;
Oro na ko ope l’ ogbon,
At’ imo Olorun.
3 Orun ni, imole wa ni,
Amona wa l’ osan;
Fitila ti nfonahan wa,
Ninu ewu oru.
4 Oro Re, oto ni titi,
Mimo ni gbogbo re:
Amona wa l’ ojo ewe,
Opa l’ ojo ogbo. Amin.