Hymn 272 Wa, Parakliti mimo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Wa, Parakliti mimo,
Lat’ ibugbe Re orun,
Ran itansan ’mole wa.
2 Baba talaka, wa ’hin,
Olufunni l’ebun, wa,
Imole okan, jo wa.
3 Baba olutunu, wa,
Alejo toto f’okan,
Pelu itura Re, wa.
4 Wo n’ isimi n’nu lala,
Iboji ninu oru,
Itunu ninu ’ponju.
5 ’Wo ’mole t’o mo gara,
Tan sinu aiya awon
Enia Re oloto.
6 Laisi Re, kil’ eda je?
Ise at’ ero mimo,
Lat’ odo Re wa ni nwon.
7 Eleri, so di mimo,
Agbogbe, ma sai wo san,
Alaileso, mu s’ eso.
8 Mu okan tutu gbona,
M’ alagidi teriba,
Fa asako wa jeje.
9 F’Emi ’jinle Re meje,
Kun awon oloto Re,
F’agbara Re s’abo won.
10 Ran or’- ofe Re sihin,
Ekun igbala l’aiye,
At’ Alafia l’orun. Amin.