Hymn 248 O ti lo. Awosanma Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 O ti lo. Awosanma,
Ti gba kuro loju wa,
Soke orun nibiti
Oju wa ko le tele;
O ti kuro l’aiye yi,
O ti de ibi mimo,
Lala at’ irora tan,
Ija tan, o ti segun.
2 O ti lo. Awa si wa
L’aiye ese at’ iku;
A ni ’se lati se fun,
L’aiye t’o ti fisile;
K’a si tele tokantokan,
K’a s’ota Re di ore,
K’a fi Kris than n’iwa wa.
3 O ti lo. On ti wipe,
“O dara ki Emi lo,”
Ni ara sa l’o ya wa,
Sugbon or’ofe Re wa:
On ni awa ko ri mo,
A ni Olutunu re,
Emi Re si je tiwa,
O ns’ agbara wa d’otun.
4 O ti lo. L’ona kanna,
L’o ye k’ Ijo Re ma lo;
K’a gbagbe ohun ehin,
K’a si ma te siwaju:
Oro Re ni ’mole wa,
Titi de opin aiye,
Nibiti oto Re wa,
Y’o pese fun alaini.
5 O ti lo. Lekan si i
A o tun f’ oju wa ri;
O wa bakanna l’orun,
Gege b’o ti wa l’aiye:
N’nu ’bugbe t’o wa nibe,
Y’o pese aye fun wa,
Ninu aiye ti mbo wa,
A o j’okan pelu Re.
6 O ti lo. Fun ire wa,
E je ki a duro de;
O jinde, ko si nihin,
O ti goke re orun;
Je k’a gb’ okan wa soke,
Sibiti Jesu ti lo,
Si odo Olorun wa,
Nibe l’alafia wa. Amin.