Hymn 244 Olorun goke lo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olorun goke lo
Pelu ariwo nla;
Awon ipe orun
Nfi ayo Angel han;
Gbogbo aiye yo, k e gberin,
E f’ ogo fun Oba Ogo.
2 O j’ enia laiye,
Oba wa ni loke;
Ki gbogbo ile mo
Ife nla Jesu wa;
Gbogbo aiye, & c
3 Baba fi agbara
Fun Jesu Oluwa;
Ogun Angel mbo O,
On l’ Oba nla orun;
Gbogbo aiye, &c;
4 L’ or’ ite Re mimo,
O gb’ opa ododo;
Gbogbo ota Re ni
Yio ka lo bere.
Gbogbo aiye, &c.;
5 Ota Re l’ ota wa,
Esu, aiye, ese;
Sugbon y’o r’ ehin won,
Ijoba Re y’o de.
Gbogbo aiye, yo k’ e gberin,
E f’ ogo fun Oba Ogo. Amin.