Hymn 233 Mo wi fun olukuluku Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Mo wi fun olukuluku
Pe, On ji, O si ye;
O si wa larin wa pelu,
Nipa Emi iye.
2 E wi fun enikeji nyin,
Kin won ji pelu wa,
K’ imole k’ o wa kakiri
Ni gbogbo aiye wa.
3 Nisisiyi aiye yi ri
Bi ile Baba wa:
Iye titun ti On fun ni,
O so d’ ile Baba.
4 Ona okun ti On ti rin
Mu ni lo si orun;
Enit o rin bi On ti rin,
Y’o d’ odo Re l’ orun.
5 On ye, O si wa pelu wa,
Ni gbogbo aiye yi;
Ati nigbat’ a f’ ara wa,
F’ erupe ni ’reti. Amin.