Hymn 215 Isimi awon mimo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Isimi awon mimo,
Ojo ohun ijinle,
Ti Eleda ti bukun,
Apere isimi Re.
Oluwa simi ’se Re,
O ya ’jo na si mimo
2 Loni oku Oluwa
Nsimi ninu iboji;
A ti we l’aso oku,
Lat’ori titi d’ese,
A si fi okuta se,
A si fi edidi di.
3 Oluwa, titi aiye,
L’a o ma pa eyi mo,
A o t’ilekun pinpin,
K’ariwo ma ba wole;
A o fi suru duro,
Tit’ Iwo o tun pada.
4 Gbogbo awon t’o ti sun,
Nwon o wa ba O simi;
Nwon o bo lowo lala,
Nwon nreti ipe ’kehin,
T’a o di eda titun,
T’ayo wa ki y’o l’opin.
5 Jesu yo wa nin’ ese,
K’a ba le ba won wole,
Ewu ati ’se y’o tan,
A o f’ayo goke lo,
A o ri Olorun wa,
A o si ma sin lailai. Amin.