Hymn 213 N’ iwaiya ’jakadi, On nikan nja Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
GETSEMANE
1 N’ iwaiya ’jakadi, On nikan nja,
O nfe iranlowo, sugbon ko ri.
2 B’ osupa ti nwo lor’ oke Olif’,
Adura tani ngoke loru yi?
3 Eje wo l’eyi ti nro bi ojo
Lat’ okan Re wa, “Eni ’banuje?”
4 Irora aileso mbe loju Re,
Ojiya ti mbebe, tan’ Iwo?
ONA IKANU
1 Gbo b’ O ti mba o soro lokan re,
“Omo ti mo ku fun, tele mi.
2 “Kin ma m’ ago ti Baba fun mi bi?
’Gbati mimu re je ’gbala re?
3 “A lu, a tuto si, a fi sefe,
A na, a si de l’ ade egun.
4 “Mo nlo si Golgota, nibe ngo ku,
’Tor’ ife mi si O; Emi ni.”
ORO MEJE LORI AGBELEBU.
1 A kan mo’gi esin, ko kerora,
O r’eru ese wa, Tire ko.
2 ’Wo Orun mi, o le wo okun bi?
Oro wo l’o nte| nu Re wa ni?
3 “Baba dariji won,” l’adura Re,
Baba si gbo, bi ’ti ma gbo ri
4 Gbo bi ole ni ti ntoro anu,
On se ’leri Paradise fun.
5 Ibatan at’ Ore rogba yika,
Maria on Magdalen r’opin re.
6 Meji ninu won di tiyatomo;
Okan t’oro Re ti so d’okan.
7 Okunkun bo ile, osan d’oru,
Iseju koja b’odun pipo.
8 Gbo ’gbe ’rora lat’ inu okun na,
“Baba, ’Wo ko mi sile, ese?
9 A! ikosile nla! iku egun!
Igbe kil’ eyi, “Ongbe ngbe mi”
10 Gbo, “O ti pari,” Ijakadi pin,
Iku at’ ipoku, a se won.
11 “Baba, gba emi mi,” l’o wi kehin,
Krist’ Oluwa iye, O si ku.
IKESI.
1 “OMo ’rora mi, ti mo f’ eje ra,
Mo gba o low’ esu, f’ Olorun;
2 “Wa alare, wa f’ori l’ aiya mi;
Sapamo sodo mi, k’o simi.
3 “Wa sodo Baba mi, wa l’ aiberu,
Alagbawi re, wa nitosi.
4 “Wa, mu ninu ore- ofe Emi:
Emi ni ini re, ’Wo t’emi.”
IDAHUN
1 Mo f’ ara mi fun O, Oluwa mi,
Sa f’ ife Re ’yebiye fun mi.
2 Gbogb’ ohun ti mo ni, t’ ara t’ okan,
Nko je fi du O, gba gbogbo re.
3 Sa ba mi gbe dopin, Oluwa mi,
Jesu, Olugbala, Emmanuel.
4 B’ akoko Re ba de, je kin yin O;
Yin O n’ ile Re titi lailai. Amin.