Hymn 197 W’ Olori Alufa Giga Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 W’ Olori Alufa Giga
B’ o ti gbe ebe wa lo;
L’ ogba, o f’ikedun wole,
O f’eru dojubole;
Angeli f’idamu duro
Lati ri Eleda be;
Awa o ha wa l’ aigbogbe,
T’a mo pe tori wa ni?
2 Kiki eje Jesu nikan
L’o le yi okan pada;
On l’o le gba wa n’nu ebi,
On l’o le m’okan wa ro:
Ofin at’ ikilo ko to,
Nwon ko si le nikan se;
Ero yi l’o le m’okan ro:
Oluwa ku dipo mi!
3 Jesu, gbogbo itunu wa,
Lat’ odo Re l’o ti nwa;
Ife, ’gbagbo, reti, suru
Gbogbo re l’eje Re ra:
Lat’ inu ekun Re l’a ngba,
A ko da ohun kan ni;
Lofe n’Iwo nfi won tore
Fun awon t’o s’ alaini. Amin.