Hymn 193 Tani le so t’ayo ti mbe Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Tani le so t’ayo ti mbe
Ni agbala Paradise;
Gbat’ amusua ba pada,
T’o si di arole ogo ?
2 Ni ayo ni Baba fi wo,
Eso ife Re ailopin;
L’ayo l’ Omo wo ’le, t’o ri
Ere iwaya- ija Re.
3 Tayotayo l’ Emi si nwo,
Okan mimo t’ On so d’otun;
Awon mimo at’ Angel nko
Orin igbile Oba won. Amin.