Hymn 191 Oluwa mo gbo pe Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa mo gbo pe, Iwo
Nro ojo ’bukun kiri;
Itunu fun okan are,
Ro ojo na sori mi
An’ emi, An’ emi,
Ro ojo na sori mi.
2 Ma koja, Baba Olore,
Bi ese mi tile po;
’Wo le fi mi sile, sugbon
Je k’anu Re ba le mi – – An’ emi.
3 Ma koja mi, Olugbala,
Je k’emi le ro mo O:
Emi nwa oju rere Re,
Pe mi mo awon t’o npe – An’ emi.
4 Ma koja mi, Emi Mimo,
’Wo le laju afoju:
Eleri itoye Jesu,
Soro ase na si mi – An’ emi.
5 Mo ti sun fonfon nin’ ese,
Mo bi O ninu koja;
Aiye ti de okan mi, jo
Tu mi k’o dariji mi – An’ emi.
6 Ife Olorun ti ki ye;
Eje Krist’ iyebiye;
Ore- ofe alainiwon;
Gbe gbogbo re ga n’nu mi – An’ emi.
7 Ma koja mi, dariji mi,
Fa mi mora, Oluwa;
’Gba o nf’ibukun f’ elomi,
Ma s’ ai f’ ibukun fun mi –
An’ emi, An’emi,
Ma s’ ai f’ ibukun fun mi. Amin.