Hymn 187 Mokandilogorun dubule je Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Mokandilogorun dubule je
Labe oji nin’ agbo;
Sugbon okan je lo or’ oke,
Jina s’ ilekun wura :
Jina rere lor’ oke sisa,
Jina rere s’ Olusagutan.
2 “Mokandilogorunn Tire l’ eyi :
Jesu, nwon ko ha to fun O?”
Olusagutan dahun, “Temi yi
Ti sako lo lodo mi;
B’ ona tile ri palapala,
Ngo w’ aginju lo w’ agutan mi”
3 Okan nin’ awon t’ a ra pada,
Ko mo jijin omi na;
Ati dudu oru ti Jesu koja,
K’ o to r’ agutan Re he;
L’ aginju rere l’o gbo ’gbe re,
O ti re tan, o si ti ku tan.
4 “Nibo ni eje ni ti nakn wa,
T’ o f’ ona or’ oke han ?
“ A ta sile f’ enikan t’o sako,
K’ Olusagutan to mu pada.”
“Jesu kil’ o gun owo Re be ?”
“Egun pupo l’ o gun mi nibe.”
5 Sugbon ni gbogbo ori oke
Ati lori apata,
Igbe ta d’ oke orun wipe,
“Yo mo r’ agutan mi he.”
Yite ka l’ awon angel ngba,
“Yo, Jesu m’ ohun Tire pada.” Amin.