Hymn 135 Gbo iro efufu, lat’ ona jijin Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Gbo iro efufu, lat’ ona jijin;
O nsoro ’jakadi ti ogun mimo;
Olorun mbe fun wa, O ti soro Re,
O sin so gbogbo nyin, “Ojise orun.”
2 Lo ! ’wo Ihinrere, ma segun titi
Okunkun ndimole, ni gbogbo aiye;
Osa nwole fun O, ile won si nwo,
Gbogb’ eda bu jewo pe, ’Wo l’ Oluwa.
3 Olugbala mimo ti njoba loke,
K’ awon om’ ogun Re ma ri O titi;
Je k’ oro Re ma tan lat’ ile de ’le,
Ki gbogbo agbaiye teriba fun O. Amin.