Hymn 132 Lo wasu ihinrere mi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Lo wasu ihinrere mi,
Mu gbogbo aiye gb’ ore mi;
Enit’ o gb’ oro mi y’o la,
Enit’ o ko yio segbe.
2 Emi o f’ oye nla han nyin,
E o f’ oro oto mi han;
Ni gbogbo ise ti mo se,
Ni gbogbo ise t’ e o se.
3 Lo wo arun, lo j’oku nde,
F’ oruko mi l’ Esu jade;
Ki woli mi mase beru,
Bi Griki ati Ju kegan.
4 Ko gbogbo aiye l’ ase mi,
Mo wa lehin nyin de opin;
Lowo mi ni gbogbo ipa,
Mo le pa, mo si le gbala.
5 Imole si ran yi i ka,
Ogo nla l’ o fi lo s’ orun;
Nwon si mu deile jijin,
Ihin igoke Olorun. Amin.