Hymn 126 Olorun ti fi Jesu se Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olorun ti fi Jesu se
Etutu fun ese;
On na l’ okan mi duro ti,
Ninu igbagbo mi.
2 Olorun si ni iyonu
Si eje Omo Re;
Omo si ti mu eje na
Wo ibi mimo lo.
3 Nibe ni eje ibuwon
Nsoro rere fun wa;
Nibe ni turari didun
Ti Alufa nla wa.
4 Angeli nwo, enu ya won;
Nwon si nteri won ba
Nitori anu Olorun
T’ o f’ eje gba ni la.
5 Emi o ma fi igbagbo
Sunmo ’bi mimo yi;
Ngo ma korin s’ Olugbala,
Ngo be k’o gb’ okan mi.
6 A ya orin mi si mimo,
Nipa eje Re na;
O si dun nipa igbagbo,
O je ’towo orun. Amin.