Hymn 124 Ilu t’ o dara po l’ aiye Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ilu t’ o dara po l’ aiye;
Betlehem, ’wo ta won yo;
Ninu re l’ Oluwa ti wa
Lati joba Israel.
2 Ogo ti irawo ni ju
Ti orun owuro lo;
Irawo t’ o kede Jesu
Ti a bi ninu ara.
3 Awon ’logbon ila- orun
Mu ’yebiye ore wa;
E wo, bi nwon ti fi wura,
Turari, ojia fun.
4 Jesu, ’Wo ti keferi nsin
Li ojo ifihan Re;
Fun O, Baba l’ a f’ ogo fun,
Ati fun Emi Mimo. Amin.