Skip to content

info@example.com

Treasure Hymns – Yoruba

  • About
  • Contact
  • Home
  • Privacy Policy
  • Sample Page
  • Terms and Conditions
  • Terms of Service
  • Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
  • About
  • Contact
  • Home
  • Privacy Policy
  • Sample Page
  • Terms and Conditions
  • Terms of Service
  • Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

Hymn 595 F’ awon Ijo ti nsimi Lyrics

  1. Home   »  
  2. Hymn 595 F’ awon Ijo ti nsimi Lyrics

Hymn 595 F’ awon Ijo ti nsimi Lyrics

December 17, 2025December 17, 2025 treasurehymnsYouruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

Hymn 595 F’ awon Ijo ti nsimi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 F’ awon Ijo ti nsimi,
Awa Ijo t’ aiye;
A f’ iyin gbogbo fun O,
Jesu Olubukun;
Oluwa, O ti segun,
Ki nwon ba le segun;
’Mole ade ogo won,
Lat’ odo Re wa ni.

St. Anderu.

A yin O, fun ’ranse Re,
Ti o ko j’ ipe Re:
T’o mu arakonrin re
Wa, lati ri Kristi;
Pese okan wa sile,
K’a sona lodun yi,
K’a m’ awon ara wa wa,
Lati ri bibo Re.

St. Tomasi.

A yin O, fun ’ranse Re,
T’ iseyemeji re,
F’ ese ’gbagbo wa mule,
T’ o si fi ’fe Re han;
Oluwa f’ alafia
F’awon ti nreti Re;
Je k’a mo O lotito,
L’ enia at’ Olorun.

St. Stefanu.

A yin O, fun ’ranse Re,
Ajeriku ’kini:
Eni, ninu wahala,
T’o nkepe Olorun;
Oluwa, b’o ba kan wa
Lati jiya fun O,
L’aiye, je k’a jeri Re,
L’ orun, je k’a gb’ ade.

St. Johannu Onihinrere.

A yin O, fun ’ranse
L’ erekusu Patmo,
A yin O, f’ eri toto,
Ti o je nipa Re.
A yin O, fun iran na,
Ti O fihan fun wa;
A o fi suru duro,
K’ a le ka wa mo won.

Ojo awon Omo were ti a pa.

A yin O, f’awon ewe,
Ajeriku mimo;
A si won lowo ogun,
Lo sibi isimi;
Rakeli, ma sokun mo,
Nwon bo lowo ’rora:
F’ okan ailetan fun wa,
K’ a gb’ ade bi ti won.

Iyipada ti St. Paulu.

A yin O, fun imole
At’ ohun lat’ orun,
A si yin O, fun iran,
Ti abinuku ri;
Ati fun ’yipada re,
A fi ogo fun O
Jo, tan ina Emi Re,
Sinu okunkun wa.

St. Mattia.

Oluwa, Iwo t’ o wa.
Pel’ awon t’ o pejo;
Iwo t’o yan Mattia
Lati ropo Juda:
A’ mbe O, gba Ijo Re
Lowo eke woli;
Rant’ ileri Re, Jesu,
Pelu ’jo Re dopin.

St. Marku.

A yin O fun ’ranse Re,
T’ Iwo f’ agbara fun;
Enit’ ihinrere re
Mu orin ’segun dun;
Ati n’nu ailera wa,
Jo je agbara wa;
Je k’a s’ eso ninu Re,
Iwo Ajara wa.

St. Filippi ati St. Jakobu.

A nyin O fun ’ranse Re,
Fillipi amona;
Ati f’ arakonrin Re,
Se wa l’ arakonrin;
Masai je k’ a le mo O,
Ona, Iye, Oto;
K’ a jeju ko idanwo,
Titi ao fi segun.

St. Barnaba.

A nyin O, fun Barnaba,
Enit’ ife Re mu
K’o ko ’hun aiye sile,
K’o wa ohun orun;
Bi aiye ti ngbile si,
Ran emi Re si wa,
Ki itunu Re toto,
Tan bo gbogbo aiye.

St. Johannu Baptisti.

A yin O, f’ Oni- baptis,
Asaju Oluwa;
Elija toto ni ’se,
Lati tun ona se.
Woli t’o ga julo ni,
O ri owuro Re;
Se wa l’ alabukunfun,
Ti nreti ojo Re.

St. Peteru.

A yin O, fun ’ranse Re,
Ogboiya ninu won;
O sebu nigba meta,
O ronupiwada;
Pelu awon alufa,
Lati toju agbo;
Si fun won ni igboiya
At’ itara pelu.

St. Jakobu.

A yin O, fun ’ranse Re,
Eniti Herod pa;
O mu ago iya Re,
O mu oro Re se;
K’ a ko iwara sile,
K’ a fi suru duro;
K’a ka iya si ayo,
B’o ba fa wa mo O.

St. Bartolomeu.

A yin O, fun ’ranse Re,
Eni oloto ni;
Enit’ oju Re ti ri,
Labe ’gi opoto.
Jo, se wa l’ alailetan,
Israeli toto;
Ki O le ma ba wa gbe,
K’ O ma bo okan wa.

St. Matteu.

A yin O, fun ’ranse Re,
T’o so ti ibi Re;
T’o ko ’hun aiye sile,
T’o yan ona iya;
Jo, da okan wa nide,
Lowo ife owo;
Je k’a le je ipe Re,
K’a nde k’a tele O.

St. Luku.

A yin O, f’ onisegun,
Ti ihinrere re,
Fi O han b’ Onisegun,
At’ Abanidaro;
Jo, f’ororo iwosan,
Si okan gbogbo wa,
At’ ikunra ’yebiye,
Kun wa nigbagbogbo.

St. Simoni ati St. Juda.

F’awon iranse Re yi,
A yin O, Oluwa;
Ife kanna l’o mu won,
Lati gb’ ona mimo;
Awa iba le jo won,
Lati gbe Jesu ga:
Ki ife so wa sokan,
K’a de ibi ’simi.

IPARI (GENERAL ENDING).

Apostili, Woli, Martyr,
Awon egbe mimo;
Nwon ko dekun orin won,
Nwon wo aso ala;
F’ awonyi t’o ti koja,
A yin O, Oluwa;
Ao tele ipase won,
A o si ma sin O.

Iyin f’ Olorun Baba,
At’ Olorun Omo,
Olorun Emi Mimo,
Metalokan Mimo;
Awon ti a ra pada,
Y’o teriba fun O;
Tire l’ ola, at’ ipa,
At’ ogo, Olorun. Amin.

Post navigation

Previous: Hymn 594 E tun won ko fun mi ki ngbo Lyrics
Next: Hymn 596 Orun ododo, jowo la Lyrics

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Hymns You May Like

  • Hymn 78 Onigbagbo, e bu s’ ayo Lyrics
  • Hymn 230 B’ elese s’ owo po Lyrics
  • Hymn 315 F’eru re f’ afefe Lyrics
  • Hymn 103 Kabiyesi ! Isun ’bukun Lyrics
  • Hymn 372 Jesu, Oba, ayo alare Lyrics
  • Hymn 596 Orun ododo, jowo la Lyrics
  • Hymn 402 Ojo nsure, o nkoja Lyrics
  • Hymn 200 Ogo ni fun Jesu Lyrics
  • Hymn 144 Okan mi, sunmo ’te anu Lyrics
  • Hymn 560 E wole f’Oba, Ologo julo Lyrics
  • Hymn 312 N’ irumi at’ iji aiye Lyrics
  • Hymn 14 Ife Re da wa si loni Lyrics
  • Hymn 501 Ji, okan mi, dide giri Lyrics
  • Hymn 544 Wa, iwo Isun ibukun Lyrics
  • Hymn 358 Nihin mo j’ alejo Lyrics
  • Hymn 535 Sa wo ite anu Lyrics
  • Hymn 235 Ojo ’mole l’eyi Lyrics
  • Hymn 213 N’ iwaiya ’jakadi, On nikan nja Lyrics
  • Hymn 138 ’Ranse Olorun, e ma kede Re Lyrics
  • Hymn 536 Jesu, nib’ eni Re pade Lyrics
  • Hymn 29 Oluwa ojo isimi Lyrics
  • Hymn 343 Fe enikeji re Lyrics
  • Hymn 587 Olugbala gbohun mi Lyrics
  • Hymn 442 Oluwa, mo mba O pade nihin Lyrics
  • Hymn 496 Oluwa, k’ a ha w’ odo Re Lyrics
  • Hymn 390 Mo f’ara Mi fun o Lyrics
  • Hymn 227 Oluwa ji loto Lyrics
  • Hymn 307 Lala mi po, nko ni ’simi laiye Lyrics
  • Hymn 51 Ojo ’binu, ojo eru Lyrics
  • Hymn 335 Jesu Oluwa, a fe O Lyrics
  • Hymn 24 Olorun wa Orun Lyrics
  • Hymn 453 Jesu a gb’ okan wa si O Lyrics
  • Hymn 234 Jesu, wa sarin wa Lyrics
  • Hymn 273 Wa mi si wa, Emi Mimo Lyrics
  • Hymn 357 Kristian, ma ti ’wa ’simi Lyrics
  • Hymn 81 Gbo eda orun nkorin Lyrics
  • Hymn 296 Bibel’ iwe aiyeraiye! Lyrics
  • Hymn 74 Gbe ori nyin s’ oke, enyin Lyrics
  • Hymn 557 Emi ’ba n’ egberun ahon Lyrics
  • Hymn 585 Jesu, o ha le je be pe Lyrics
  • Hymn 175 Otosi elese, e wa Lyrics
  • Hymn 576 Kristi n’ ipile wa Lyrics
  • Hymn 283 Baba orun, ’jinle ’fe Re Lyrics
  • Hymn 17 L’ oju ale, ’gbat ’orun wo Lyrics
  • Hymn 118 Lat’ oke tutu Grinland Lyrics
  • Hymn 458 Jesu, ’Wo onirele Lyrics
  • Hymn 182 Are mu o, aiye su o Lyrics
  • Hymn 264 Olurapada wa, k’On to Lyrics
  • Hello world!
  • Hymn 241 Wo Asegun b’o ti goke Lyrics
  • Hymn 48 Gbo ’gbe ayo ! Oluwa de Lyrics
  • Hymn 151 Jesu mi, mu mi gb’ ohun Re Lyrics
  • Hymn 163 Oluwa, b’ agbowode ni Lyrics
  • Hymn 294 Iwe kan wa ti kika re Lyrics
  • Hymn 122 Elese, wa sodo Jesu Lyrics
  • Hymn 120 Oluwa y’o tip e to Lyrics
  • Hymn 444 ‘K’ On to de, – je k’oro yi Lyrics
  • Hymn 204 Wo Odagutan ti o ru Lyrics
  • Hymn 166 Kristi t’ agbelebu l’ orin wa Lyrics
  • Hymn 457 Wa, Emi Mimo, wa Lyrics

Archives

  • December 2025

Categories

  • Uncategorized
  • Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
Proudly powered by WordPress | Theme: goldy-mex by inverstheme.
Go to mobile version