Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 99 Oluwa alafia wa Lyrics

Hymn 99 Oluwa alafia wa Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Oluwa alafia wa
L’o pase t’ odun yipo;
Awa omo Re wa dupe
F’ Odun titun t’ a bere.
Yin Oluwa ! Yin Oluwa !
Oba nla t’o da wa si.

2 A dupe fun ipamo wa
Ni odun ti o koja;
A mbebe iranlowo Re
Fun gbogbo wa lodun yi.
Je k’ Ijo wa, Je k’ Ijo wa
Ma dagba ninu Kristi.

3 K’ agba k’o mura lati sin
Lokan kan ni odun yi;
K’ awon omode k’o mura
Lati saferi Jesu.
K’ alafia, K’ alafia
K’o se ade odun yi.

4 K’ Emi Mimo lat’ oke wa
Ba le wa ni odun yi;
Ki Alufa at’ Oluko
Pelu gbogbo Ijo wa
Mura giri, Mura giri
Lati josin f’ Oluwa. Amin.

Exit mobile version