Hymn 98 Olorun Betel, eniti Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olorun Betel, eniti
O mbo awon Tire;
Enit’ o mu baba wa la
Ojo aiye won ja.
2 A mu eje at’ ebe wa
Wa iwaju ‘te Re,
Olorun awon baba wa,
Ma je Olorun wa.
3 Ninu idamu aiye yi,
Ma toju ipa wa;
Fun wa ni onje ojo wa,
At’ aso t’ o ye wa.
4 Na ojiji ‘ye Re bow a,
Tit’ ajo wa o pin,
Ati ni ‘bugbe Baba wa,
Okan wa o simi.
5 Iru ibukun bi eyi,
L’ a mbere lowo rE;
Iwo o je Olorun wa
At’ ipin wa lailai. Amin.